Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 12:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro;

6. kí ẹ̀wọ̀n fadaka tó já, kí àwo wúrà tó fọ́; kí ìkòkò tó fọ́ níbi orísun omi, kí okùn ìfami tó já létí kànga;

7. kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.

8. Asán ninu asán, ọ̀jọ̀gbọ́n ní, asán ni gbogbo rẹ̀.

9. Yàtọ̀ sí pé ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbọ́n, ó tún kọ́ àwọn eniyan ní ìmọ̀. Ó wádìí àwọn òwe fínnífínní, ó sì tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ.

10. Ó wádìí ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára ati ọ̀rọ̀ òdodo, ó sì kọ wọ́n sílẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn.

11. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ òwe tí olùṣọ́-aguntan kan bá sọ dàbí ìṣó tí a kàn tí ó dúró gbọningbọnin.

12. Ọmọ mi, ṣọ́ra fún ohunkohun tí ó bá kọjá eléyìí, ìwé kíkọ́ kò lópin, àkàjù ìwé a sì máa kó àárẹ̀ bá eniyan.

13. Kókó gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni ohun tí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan.

14. Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 12