Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 12:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.”

2. Kí oòrùn ati ìmọ́lẹ̀ ati òṣùpá ati ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, kí ìkùukùu tó pada lẹ́yìn òjò;

3. nígbà tí àwọn tí ń ṣọ́ ilé yóo máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí ẹ̀yìn àwọn alágbára yóo tẹ̀, tí àwọn òòlọ̀ yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí pé wọn kò pọ̀ mọ́, tí àwọn tí ń wo ìta láti ojú fèrèsé yóo máa ríran bàìbàì;

4. tí àwọn ìlẹ̀kùn yóo tì ní ìgboro, tí ariwo òòlọ̀ yóo rọlẹ̀, tí ohùn ẹyẹ lásán yóo máa jí eniyan kalẹ̀, tí àwọn ọdọmọbinrin tí wọn ń kọrin yóo dákẹ́;

5. ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro;

6. kí ẹ̀wọ̀n fadaka tó já, kí àwo wúrà tó fọ́; kí ìkòkò tó fọ́ níbi orísun omi, kí okùn ìfami tó já létí kànga;

7. kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.

8. Asán ninu asán, ọ̀jọ̀gbọ́n ní, asán ni gbogbo rẹ̀.

9. Yàtọ̀ sí pé ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbọ́n, ó tún kọ́ àwọn eniyan ní ìmọ̀. Ó wádìí àwọn òwe fínnífínní, ó sì tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ.

10. Ó wádìí ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára ati ọ̀rọ̀ òdodo, ó sì kọ wọ́n sílẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn.

11. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ òwe tí olùṣọ́-aguntan kan bá sọ dàbí ìṣó tí a kàn tí ó dúró gbọningbọnin.

12. Ọmọ mi, ṣọ́ra fún ohunkohun tí ó bá kọjá eléyìí, ìwé kíkọ́ kò lópin, àkàjù ìwé a sì máa kó àárẹ̀ bá eniyan.

13. Kókó gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni ohun tí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 12