Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 10:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́;bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́.

2. Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere,ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí.

3. Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n,a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó.

4. Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ,má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ,ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini.

5. Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe:

6. Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀.

7. Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.

8. Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀,ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ.

9. Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára;ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.

10. Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú,yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó,ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí.

11. Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán,kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò.

12. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un,ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á.

13. Agọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,wèrè sì ni ìparí rẹ̀.

14. Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́,kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la,ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un.

15. Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a,tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́.

16. Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 10