Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 48:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan.

2. Ìpín ti Aṣeri yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Dani, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

3. Ìpín ti Nafutali yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Aṣeri, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

4. Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,

5. Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

6. Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

7. Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

8. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Juda ni ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo wà. Ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12.5), òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà pẹlu ti àwọn ìpín yòókù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ibi mímọ́ yóo wà láàrin rẹ̀.

9. Òòró ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ (kilomita 10).

Ka pipe ipin Isikiẹli 48