Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 48:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan.

2. Ìpín ti Aṣeri yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Dani, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

3. Ìpín ti Nafutali yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Aṣeri, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

4. Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,

5. Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

6. Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

7. Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 48