Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 42:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nísàlẹ̀ àwọn yàrá ìhà gúsù, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn. Bí eniyan bá wọ àlàfo náà, ògiri kan dábùú rẹ̀ níwájú.

13. Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́.

14. Nígbà tí àwọn alufaa bá wọ ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ jáde sí gbọ̀ngàn ìta láìbọ́ aṣọ tí wọ́n lò sinu yàrá wọnyi, nítorí pé aṣọ mímọ́ ni wọ́n. Wọ́n gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọ́n tó súnmọ́ àwọn ohun tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan.”

15. Nígbà tí ó ti parí wíwọn inú Tẹmpili, ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn jáde, ó sì wọn ẹ̀yìn Tẹmpili yíká.

16. Ó wọn apá ìlà oòrùn pẹlu ọ̀pá rẹ̀, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.

17. Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà àríwá, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.

18. Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà gúsù, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.

19. Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn apá ìwọ̀ oòrùn, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.

20. Ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ni ó wọ̀n. Tẹmpili náà ní ògiri yíká, òòró rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), èyí ni ó jẹ́ ààlà láàrin ibi mímọ́ ati ibi tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan.

Ka pipe ipin Isikiẹli 42