Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 41:10-26 BIBELI MIMỌ (BM)

10. ati àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ gbọ̀ngàn fẹ̀ ní ogún igbọnwọ (mita 10), yíká gbogbo ẹ̀gbẹ́ tẹmpili.

11. Àwọn ìlẹ̀kùn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ṣí sí apá pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀. Ìlẹ̀kùn kan kọjú sí ìhà àríwá, ekeji kọjú sí ìhà gúsù. Ìbú pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká.

12. Ilé tí ó kọjú sí àgbàlá Tẹmpili ní apá ìwọ̀ oòrùn fẹ̀ ní aadọrin igbọnwọ (mita 35), ògiri ilé náà nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká, òòró rẹ̀ sì jẹ́ aadọrun-un igbọnwọ (mita 45).

13. Lẹ́yìn náà, ó wọn Tẹmpili, ó gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Àgbàlá ati ilé náà pẹlu ògiri rẹ̀ gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

14. Bákan náà ni gígùn iwájú tẹmpili tí ó kọjú sí ìlà oòrùn ati àgbàlá, òun náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

15. Lẹ́yìn náà, ó wọn òòró ilé ní ìhà tí ó dojú kọ àgbàlá tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ati àwọn ògiri rẹ̀; ẹ̀gbẹ́ kinni keji gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).Pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni wọ́n fi bo ara ògiri ibi mímọ́ jùlọ Tẹmpili náà ati yàrá inú ati

16. ìloro ti ìta yíká. Àwọn mẹtẹẹta ní fèrèsé aláṣìítì. Wọ́n fi pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo ara ògiri Tẹmpili náà yíká láti ilẹ̀ títí kan ibi fèrèsé, títí kọjá ìloro. (Wọ́n fi pákó bo àwọn fèrèsé náà).

17. Ati ààyè tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà, títí kan yàrá inú pàápàá, ati ẹ̀yìn ìta. Gbogbo ara ògiri yàrá inú yíká ati ibi mímọ́ ni wọ́n gbẹ́

18. àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí yíká; wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan sí ààrin kerubu meji meji.

19. Kerubu kọ̀ọ̀kan ní iwájú meji meji. Iwájú tí ó dàbí ti eniyan kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ekeji tí ó dàbí ti ọ̀dọ́ kinniun kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ keji. Wọ́n gbẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ sí ara Tẹmpili yíká.

20. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ògiri náà láti ilẹ̀ títí dé òkè ìlẹ̀kùn.

21. Àwọn òpó ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn ti òde ibi mímọ́ jùlọ ní igun mẹrin, òòró ati ìbú ìlẹ̀kùn wọn sì dọ́gba.Kinní kan tí ó dàbí

22. pẹpẹ tí a fi igi ṣe wà níwájú ibi mímọ́. Gíga rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta (mita 1½), òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Igi ni wọ́n fi ṣe igun rẹ̀, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati ara rẹ̀. Ọkunrin náà sọ fún mi pé: “Èyí ni tabili tí ó wà níwájú OLUWA.”

23. Ibi mímọ́ jùlọ, ati ibi mímọ́ ní ìlẹ̀kùn meji meji.

24. Àwọn ìlẹ̀kùn náà ní awẹ́ meji meji. Awẹ́ meji meji tí ó ṣe é ṣí láàrin ni ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní.

25. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ jùlọ, bí èyí tí wọ́n gbẹ́ sí ara àwọn ògiri. Ìbòrí kan tí a fi pákó ṣe wà níwájú ìloro ní ìta.

26. Àwọn fèrèsé aláṣìítì, tí wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ sí lára, wà lára ògiri ìloro náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji.

Ka pipe ipin Isikiẹli 41