Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 40:44-49 BIBELI MIMỌ (BM)

44. Lẹ́yìn náà ó mú mi wọ gbọ̀ngàn ti inú. Mo rí yàrá meji ninu gbọ̀ngàn yìí: ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ó dojú kọ ìhà gúsù, ekeji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìhà gúsù, ó dojú kọ ìhà àríwá.

45. Ó wí fún mi pé àwọn alufaa tí ń mójútó tẹmpili ni wọ́n ni yàrá tí ó kọjú sí ìhà gúsù.

46. Yàrá tí ó kọjú sí ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn alufaa tí wọn ń mójútó pẹpẹ; àwọn ni àwọn ọmọ Sadoku. Àwọn nìkan ninu ìran Lefi ni wọ́n lè súnmọ́ OLUWA láti rúbọ sí i.

47. Ó wọn gbọ̀ngàn ti inú, òòró rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45), igun rẹ̀ mẹrẹẹrin dọ́gba, pẹpẹ sì wà níwájú tẹmpili.

48. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìloro tẹmpili, ó sì wọn àtẹ́rígbà rẹ̀. Ó jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un (mita 2½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji; ìbú ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita 7). Àwọn ògiri rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta mẹta (mita 1½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji.

49. Òòró ìloro náà jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita 5½), àtẹ̀gùn rẹ̀ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, òpó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ́rígbà rẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 40