Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 40:35-43 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ibi ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá, ó sì wọ̀n ọ́n, bákan náà ni òun náà rí pẹlu àwọn yòókù.

36. Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

37. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

38. Yàrá kan wà tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ninu ìloro ẹnu ọ̀nà, níbẹ̀ ni wọ́n tí ń fọ ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun.

39. Tabili meji meji wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà, lórí wọn ni wọ́n tí ń pa àwọn ẹran ẹbọ sísun, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

40. Tabili meji wà ní ìta ìloro náà, ní ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá, tabili meji sì tún wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà.

41. Tabili mẹrin wà ninu, mẹrin sì wà ní ìta, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà; gbogbo rẹ̀ jẹ́ tabili mẹjọ. Lórí wọn ni wọ́n tí ń pa ẹran ìrúbọ.

42. Tabili mẹrin kan tún wà tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ìbú rẹ̀ náà jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ó sì ga ní igbọnwọ kan (bíi ìdajì mita). Lórí rẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran ẹbọ sísun ati ti ẹbọ yòókù sí.

43. Wọ́n kan àwọn ìkọ́ kan tí ó gùn ní ìwọ̀n àtẹ́lẹwọ́ kan mọ́ ara tabili yíká ninu. Wọn a máa gbé ẹran tí wọn yóo bá fi rúbọ lé orí àwọn tabili náà.

Ka pipe ipin Isikiẹli 40