Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 4:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú bulọọku kan kí o gbé e ka iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sórí rẹ̀.

2. Kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń dóti ìlú tì í. Bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ọ̀nà dé ibẹ̀. Fi àgọ́ àwọn jagunjagun sí i, kí o wá gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká.

3. Wá irin pẹlẹbẹ kan tí ó fẹ̀, kí o gbé e sí ààrin ìwọ ati ìlú náà, kí ó dàbí ògiri onírin. Dojú kọ ọ́ bí ìlú tí a gbógun tì; kí o ṣebí ẹni pé ò ń gbógun tì í. Èyí yóo jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.

4. “Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀.

5. Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.

6. Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.

7. “Lẹ́yìn náà, kọjú sí Jerusalẹmu, ìlú tí a gbógun tì, ká aṣọ kúrò ní apá rẹ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i.

8. Wò ó! N óo dè ọ́ lókùn mọ́lẹ̀, tí o kò fi ní lè yí ẹ̀gbẹ́ pada títí tí o óo fi parí iye ọjọ́ tí o níláti fi gbé ogun tì í.

9. “Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.

10. Wíwọ̀n ni o óo máa wọn oúnjẹ tí o óo máa jẹ, ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ rẹ yóo jẹ́ ogún ṣekeli, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa jẹ ẹ́.

11. Wíwọ̀n ni o óo máa wọn omi tí o óo máa mu pẹlu; ìdá mẹfa òṣùnwọ̀n hini ni omi tí o óo máa mu ní ọjọ́ kan, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa mu ún.

Ka pipe ipin Isikiẹli 4