Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 39:7-9 BIBELI MIMỌ (BM)

7. N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ”

8. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé.

9. Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n.

Ka pipe ipin Isikiẹli 39