Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 39:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀.

18. Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani.

19. Ẹ óo jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó ní ibi àsè tí n óo sè fun yín.

20. Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

21. “N óo fi ògo mi hàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn ni yóo sì rí irú ẹjọ́ tí mo dá wọn ati irú ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.

22. Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọ Israẹli óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

23. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli dá tí wọ́n fi di ẹni tí ó lọ sí ìgbèkùn, ati pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi ni mo ṣe dijú sí wọn, tí mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi idà pa wọ́n.

24. Bí àìmọ́ ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo fìyà jẹ wọ́n tó, mo sì gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn.”

25. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli n óo kó àwọn ọmọ Jakọbu pada láti oko ẹrú, n óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì jowú nítorí orúkọ mímọ́ mi.

Ka pipe ipin Isikiẹli 39