Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 38:9-23 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ óo gbéra, ẹ óo máa bọ̀ bí ìjì líle, ẹ óo dàbí ìkùukùu tí ó bo ilẹ̀, ìwọ ati gbogbo ọmọ ogun rẹ, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tí ó wà pẹlu rẹ.”

10. OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ náà èròkerò yóo wá sí ọkàn rẹ,

11. o óo wí ninu ara rẹ pé, ‘N óo gbógun ti ilẹ̀ tí kò ní odi yìí; n óo kọlu àwọn tí wọ́n jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ wọn láìléwu, gbogbo wọn ń gbé ìlú tí kò ní odi, kò sì ní ìlẹ̀kùn, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn.’

12. N óo lọ kó wọn lẹ́rù, n óo sì kó ìkógun. N óo kọlu àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro nígbà kan rí, ṣugbọn tí àwọn eniyan ń gbé ibẹ̀ nisinsinyii, àwọn eniyan tí a ṣà jọ láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, ṣugbọn tí wọ́n ní mààlúù ati ohun ìní, tí wọ́n sì ń gbé ìkóríta ilẹ̀ ayé.

13. Ṣeba ati Dedani ati àwọn oníṣòwò Taṣiṣi, ati àwọn ìlú agbègbè wọn yóo bi ọ́ pé, ‘Ṣé o wá kó ìkógun ni, ṣé o kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ láti wá kó ẹrú, fadaka ati wúrà, ati mààlúù, ọrọ̀ ati ọpọlọpọ ìkógun?’ ”

14. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí pé, OLUWA Ọlọrun ní: “Ní ọjọ́ tí àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, bá ń gbé láìléwu, ìwọ óo gbéra ní ààyè rẹ

15. ní ọ̀nà jíjìn, ní ìhà àríwá, ìwọ ati ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn lórí ẹṣin, ọpọlọpọ eniyan, àní, àwọn ọmọ ogun.

16. O óo kọlu àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan mi, bí ìkùukùu tí ń ṣú bo ilẹ̀. Nígbà tí ó bá yà n óo mú kí o kọlu ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè mọ̀ mí nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ ìwọ Gogu fi bí ìwà mímọ́ mi ti rí hàn níṣojú wọn.

17. OLUWA ní: ṣé ìwọ ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ láti ẹnu àwọn wolii Israẹli, àwọn iranṣẹ mi, tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọpọlọpọ ọdún pé n óo mú ọ wá láti gbógun tì wọ́n?

18. “Ṣugbọn ní ọjọ́ tí Gogu bá gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, inú mi óo ru. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19. Pẹlu ìtara ati ìrúnú ni mo fi ń sọ pé ilẹ̀ Israẹli yóo mì tìtì ní ọjọ́ náà.

20. Àwọn ẹja inú omi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko inú igbó, gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ati gbogbo eniyan tí ó wà láyé yóo wárìrì. Àwọn òkè yóo wó lulẹ̀, àwọn òkè etí òkun yóo ṣubú sinu òkun. Gbogbo odi ìlú yóo sì wó lulẹ̀.

21. N óo dá oríṣìíríṣìí ẹ̀rù ba Gogu, lórí òkè mi, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo fa idà yọ sí ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22. N óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú ogun ṣe ìdájọ́ wọn. N óo rọ òjò yìnyín, iná, ati imí ọjọ́ lé òun, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan pupọ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lórí.

23. N óo fi títóbi mi ati ìwà mímọ́ mi hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 38