Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 37:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró!

11. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọ Israẹli ni àwọn egungun wọnyi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ; kò sí ìrètí fún wa mọ́, a ti pa wá run patapata.’

12. Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli.

13. Ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ṣí ibojì yín, tí mo sì gbe yín dìde, ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

Ka pipe ipin Isikiẹli 37