Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 36:23-38 BIBELI MIMỌ (BM)

23. N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n.

24. Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín.

25. N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.

26. N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara.

27. N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́.

28. Ẹ óo sì máa gbé orí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun yín.

29. N óo gbà yín kúrò ninu gbogbo ìwà èérí yín. N óo mú ọkà pọ̀ ní ilé yín, n kò sì ní jẹ́ kí ìyàn mu yín mọ́.

30. N óo jẹ́ kí èso igi ati èrè oko pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ìtìjú kò ní ba yín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ nítorí ìyàn.

31. Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín.

32. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé kì í ṣe nítorí yín ni n óo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ojú tì yín, kí ẹ sì dààmú nítorí ìwà yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

33. OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, n óo jẹ́ kí àwọn eniyan máa gbé inú àwọn ìlú yín, n óo sì mú kí wọ́n tún àwọn ibi tí ó wó lulẹ̀ kọ́.

34. A óo dá oko sórí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti di igbó, dípò kí ó máa wà ní igbó lójú àwọn tí wọn ń kọjá lọ.

35. Wọn yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ yìí, tí ó ti jẹ́ igbó nígbà kan rí, ti dàbí ọgbà Edẹni, àwọn eniyan sì ti ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n ti wó lulẹ̀, tí wọ́n ti di ahoro, tí wọ́n sì ti run tẹ́lẹ̀; a sì ti mọ odi wọn pada.’

36. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA ni mo tún àwọn ibùgbé yín tí ó wó lulẹ̀ kọ́, tí mo sì tún gbin nǹkan ọ̀gbìn sí ilẹ̀ yín tí ó di igbó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”

37. OLUWA Ọlọrun ní, “Ohun kan tí n óo tún mú kí àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí n ṣe fún àwọn ni pé kí n máa mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ sí i bí ọ̀wọ́ aguntan.

38. Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 36