Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 36:17-28 BIBELI MIMỌ (BM)

17. “Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́.

19. Mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì tú káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Ìwà ati ìṣe wọn ni mo fi dá wọn lẹ́jọ́.

20. Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, wọ́n bà mí lórúkọ jẹ́, nítorí àwọn eniyan ń sọ nípa wọn pé, ‘Eniyan OLUWA ni àwọn wọnyi, sibẹsibẹ wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ OLUWA.’

21. Ṣugbọn mo ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi, tí àwọn ọmọ Israẹli sọ di nǹkan yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà.

22. “Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ.

23. N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n.

24. Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín.

25. N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.

26. N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara.

27. N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́.

28. Ẹ óo sì máa gbé orí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun yín.

Ka pipe ipin Isikiẹli 36