Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 36:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

12. N óo jẹ́ kí àwọn eniyan mi, àní àwọn ọmọ Israẹli, máa rìn bọ̀ lórí yín. Àwọn ni wọn óo ni yín, ẹ óo sì di ogún wọn, ẹ kò ní pa wọ́n lọ́mọ mọ́.

13. “Nítorí àwọn eniyan ń wí pé ò ń paniyan, ati pé ò ń run àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ.

14. Nítorí náà, o kò ní pa eniyan mọ́, o kò sì ní pa àwọn eniyan rẹ lọ́mọ mọ́, Èmi OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

15. N kò ní jẹ́ kí o gbọ́ ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan kò ní dójútì ọ́ mọ́, n kò sì ní mú kí orílẹ̀-èdè rẹ kọsẹ̀ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

16. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

17. “Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́.

19. Mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì tú káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Ìwà ati ìṣe wọn ni mo fi dá wọn lẹ́jọ́.

Ka pipe ipin Isikiẹli 36