Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 25:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. N óo ṣe ìdájọ́ àwọn ará Moabu; wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!”

12. OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí àwọn ará Edomu gbẹ̀san lára àwọn ará Juda, wọ́n sì ṣẹ̀ nítorí ẹ̀san tí wọ́n gbà.

13. N óo nawọ́ ìyà sí Edomu, n óo pa ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀ run. N óo sọ ọ́ di ahoro láti Temani títí dé Dedani. Ogun ni yóo pa wọ́n.

14. Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Filistia gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn, wọn sì fi ìkórìíra àtayébáyé pa wọ́n run,

16. nítorí náà, n óo nawọ́ ìyà sí wọn, n óo pa àwọn ọmọ Kereti run, n óo pa àwọn tí ó kù sí etí òkun rẹ́.

17. N óo gbẹ̀san lára wọn lọpọlọpọ; n óo fi ìrúnú fi ìyà ńlá jẹ wọ́n. Wọn óo wá mọ̀ nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 25