Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 25:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí àwọn ará Amoni kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn.

3. Wí fún wọn báyìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí; nítorí pé ẹ̀ ń yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ẹ̀ ń yọ ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ẹ sì ń yọ ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n kó o lọ sí ìgbèkùn;

4. nítorí náà, n óo fà yín lé àwọn ará ilẹ̀ ìlà oòrùn lọ́wọ́, ẹ óo sì di tiwọn. Wọn óo pa àgọ́ sí ààrin yín; wọn óo tẹ̀dó sí ààrin yín; wọn óo máa jẹ èso oko yín, wọn óo sì máa mu wàrà yín.

5. N óo sọ ìlú Raba di pápá àwọn ràkúnmí, àwọn ìlú Amoni yóo sì di pápá ẹran. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!’

6. Nitori báyìí ni OLUWA Ọlọrun wí, “Ẹ̀yin ń pàtẹ́wọ́, ẹ̀ ń fò sókè, ẹ sì ń yọ àwọn ọmọ Israẹli.

7. Nítorí náà, ẹ wò ó! Mo ti nawọ́ ìyà si yín, n óo sì fi yín ṣe ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. N óo pa yín run láàrin àwọn eniyan ilẹ̀ ayé, n óo sì pa yín rẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

8. OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Moabu ń wí pé ilẹ̀ Juda dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

9. nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká.

Ka pipe ipin Isikiẹli 25