Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 24:14-24 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16. “Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ.

17. O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.”

18. Mo bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ láàárọ̀, nígbà tí ó di àṣáálẹ́, iyawo mi kú. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí n ṣe.

19. Àwọn eniyan bá bi mí pé, “Ṣé kò yẹ kí o sọ ohun tí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa, tí o fi ń ṣe báyìí.”

20. Mo bá sọ fún wọn pé, “OLUWA ni ó bá mi sọ̀rọ̀,

21. tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀.

22. Bí mo ti ṣe yìí gan-an ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe, ẹ kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu yín tabi kí ẹ máa jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.

23. Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn.

24. Ó ní èmi Isikiẹli óo jẹ́ àmì fun yín, gbogbo bí mo bá ti ṣe ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹlẹ̀. Ẹ óo sì mọ̀ pé òun ni OLUWA Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 24