Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 22:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ǹjẹ́ o lè ní ìgboyà ati agbára ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.

15. N óo fọn yín káàkiri ààrin àwọn àjèjì; n óo tu yín ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo fi òpin sí ìwà èérí tí ẹ̀ ń hù ní Jerusalẹmu.

16. N óo di ẹni ìdọ̀tí lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí rẹ, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

17. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

18. “Ìwọ ọmọ eniyan; àwọn ọmọ Israẹli ti di ìdàrọ́ lójú mi. Wọ́n dàbí idẹ, páànù, irin, ati òjé tí ó wà ninu iná alágbẹ̀dẹ. Wọ́n dàbí ìdàrọ́ ara fadaka.

19. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní níwọ̀n ìgbà tí gbogbo yín ti di ìdàrọ́, n óo ko yín jọ sí ààrin Jerusalẹmu.

20. Bí eniyan ṣe ń kó fadaka, idẹ, irin, òjé ati páànù pọ̀ sinu ìkòkò lórí iná alágbẹ̀dẹ, kí wọ́n lè yọ́, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu ati ìrúnú ko yín jọ n óo sì yọ yín.

21. N óo ko yín jọ, n óo fẹ́ ìrúnú mi si yín lára bí iná, ẹ óo sì yọ́.

22. Bí wọn tí ń yọ́ fadaka ninu iná alágbẹ̀dẹ, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu yọ yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo bínú si yín.”

23. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

24. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ilẹ̀ tí kò mọ́ ni ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí lákòókò ibinu èmi OLUWA.

25. Àwọn olórí tí wọ́n wà nílùú dàbí kinniun tí ń bú, tí ó sì ń fa ẹran ya. Wọ́n ti jẹ àwọn eniyan run, wọ́n ń fi ipá já ohun ìní ati àwọn nǹkan olówó iyebíye gbà, wọ́n ti sọ ọpọlọpọ obinrin di opó nílùú.

Ka pipe ipin Isikiẹli 22