Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 21:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. “Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn.

7. Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

8. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

9. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní:Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa.

10. A ti pọ́n ọn láti fi paniyan;a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná.Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá;nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi.

11. Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á,kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́.

12. Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún,nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí;ati àwọn olórí ní Israẹli.Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi.Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu.

13. Mò ń dán àwọn eniyan mi wò,bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada,gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn,Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

14. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí.

15. Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á.

16. Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí.

17. Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 21