Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 21:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli.

3. Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú.

4. N óo pa àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú tí ó wà ninu rẹ run, nítorí náà, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo eniyan láti ìhà gúsù títí dé ìhà àríwá.

5. Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo fa idà mi yọ, n kò sì ní dá a pada sinu àkọ̀ mọ́.’

6. “Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn.

7. Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

8. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

9. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní:Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa.

10. A ti pọ́n ọn láti fi paniyan;a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná.Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá;nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi.

11. Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á,kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́.

12. Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún,nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí;ati àwọn olórí ní Israẹli.Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi.Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu.

13. Mò ń dán àwọn eniyan mi wò,bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada,gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn,Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 21