Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 20:21-29 BIBELI MIMỌ (BM)

21. “Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀.

22. Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.

23. Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

24. nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ.

25. “Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là.

26. Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

27. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

28. Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀.

29. Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní.

Ka pipe ipin Isikiẹli 20