Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 20:17-26 BIBELI MIMỌ (BM)

17. “Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀.

18. Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn.

19. Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́.

20. Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín.

21. “Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀.

22. Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.

23. Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

24. nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ.

25. “Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là.

26. Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

Ka pipe ipin Isikiẹli 20