Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 2:7-10 BIBELI MIMỌ (BM)

7. O óo sọ ohun tí mo bá wí fún wọn, wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má gbọ́; nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n.

8. “Ṣugbọn ìwọ, ọmọ eniyan, fetí sí ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má dìtẹ̀ bí àwọn ọmọ ìdílé ọlọ̀tẹ̀ wọnyi. La ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí n óo fún ọ.”

9. Nígbà tí mo wò, mo rí ọwọ́ tí ẹnìkan nà sí mi, ìwé kan tí a ká sì wà ninu rẹ̀.

10. Ó tẹ́ ìwé náà siwaju mi; mo sì rí i pé wọ́n kọ nǹkan sí i ní àtojú àtẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ ẹkún, ati ọ̀rọ̀ ọ̀fọ̀, ati ègún ni wọ́n kọ sinu rẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 2