Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 12:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.

15. “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé.

16. N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

17. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

18. “Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ.

19. Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù.

20. Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

21. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

22. “Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’

23. Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ.

Ka pipe ipin Isikiẹli 12