Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 12:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

3. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

4. Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn.

5. Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde.

6. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.”

7. Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn.

8. Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀,

9. ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe?

10. Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’

Ka pipe ipin Isikiẹli 12