Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 11:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀.

19. Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;

20. kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

21. Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

22. Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

23. Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà.

24. Ẹ̀mí bá gbé mi sókè ní ojúran, ó gbé mi wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ìran tí mo rí bá kúrò lójú mi.

25. Mo sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA fihàn mí fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 11