Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 9:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọ́n ti sọ ara wọn di aláìmọ́ lọpọlọpọ, bí ìgbà tí wọ́n wà ní Gibea. Ọlọrun yóo ranti àìdára tí wọ́n ṣe, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

10. OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn.

11. Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn!

12. Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!”

13. Mo rí àwọn ọmọ Efuraimu bí ẹran àpajẹ; Efuraimu gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa.

14. Fún wọn ní nǹkankan, OLUWA, OLUWA, kí ni ò bá tilẹ̀ fún wọn? Jẹ́ kí oyún máa bàjẹ́ lára obinrin wọn, kí ọmú wọn sì gbẹ.

15. OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn.

16. Ìyà jẹ Efuraimu, gbòǹgbò wọn ti gbẹ, wọn kò sì ní so èso mọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, n óo pa àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ràn.”

17. Ọlọrun mi yóo pa wọ́n run, nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; wọn yóo di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

Ka pipe ipin Hosia 9