Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 8:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí pé wọ́n lọ sí Asiria, wọ́n dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń dá rìn; Efuraimu ti bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wẹ̀ fún ààbò.

10. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo kó wọn jọ láìpẹ́, láti jẹ wọ́n níyà, fún ìgbà díẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn ọba alágbára tí yóo ni wọ́n lára.

11. “Nítorí Efuraimu ti tẹ́ ọpọlọpọ pẹpẹ láti dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, wọ́n ti di pẹpẹ ẹ̀ṣẹ̀ dídá fún un.

12. Bí mo tilẹ̀ kọ òfin mi sílẹ̀ ní ìgbà ẹgbẹrun, sibẹsibẹ wọn óo kà wọ́n sí nǹkan tó ṣàjèjì.

13. Wọ́n fẹ́ràn ati máa rúbọ; wọ́n ń fi ẹran rúbọ, wọ́n sì ń jẹ ẹ́; ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí wọn. Yóo wá ranti àìdára wọn nisinsinyii, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọn óo sì pada sí Ijipti.

14. “Àwọn ọmọ Israẹli ti gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ti kọ́ ààfin fún ara wọn. Àwọn ọmọ Juda ti kọ́ ọpọlọpọ ìlú olódi sí i; ṣugbọn n óo sọ iná sí àwọn ìlú wọn, yóo sì jó àwọn ibi ààbò wọn ní àjórun.”

Ka pipe ipin Hosia 8