Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 5:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Mo mọ Efuraimu, bẹ́ẹ̀ ni Israẹli kò ṣàjèjì sí mi; nisinsinyii, ìwọ Efuraimu ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, Israẹli sì ti di aláìmọ́.”

4. Gbogbo ibi tí wọn ń ṣe, kò jẹ́ kí wọ́n lè pada sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, nítorí pé ọkàn wọn kún fún ẹ̀mí àgbèrè, wọn kò sì mọ OLUWA.

5. Ìgbéraga Israẹli hàn kedere lójú rẹ̀; Efuraimu yóo kọsẹ̀, yóo sì ṣubú ninu ìwà burúkú rẹ̀, Juda náà yóo ṣubú pẹlu wọn.

6. Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn.

7. Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn.

8. Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini!

Ka pipe ipin Hosia 5