Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 11:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. “Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.

6. A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn.

7. Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ.

8. “Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu?Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli?Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run;kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu?Ọkàn mi kò gbà á,àánú yín a máa ṣe mí.

9. N kò ní fa ibinu yọ mọ́,n kò ní pa Efuraimu run mọ́,nítorí pé Ọlọrun ni mí,n kì í ṣe eniyan,èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín,n kò sì ní pa yín run.

10. “Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn;

Ka pipe ipin Hosia 11