Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hagai 1:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀.

10. Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ.

11. Mo mú ọ̀gbẹlẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ati sórí àwọn òkè, ati oko ọkà, ati ọgbà àjàrà ati ọgbà igi olifi. Bẹ́ẹ̀ náà ló kan gbogbo ohun tí ń hù lórí ilẹ̀, ati eniyan ati ẹran ọ̀sìn, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan.”

12. Ni Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa, ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù bá gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun wọn lẹ́nu, wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wolii Hagai, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wọn ti rán an; wọ́n sì bẹ̀rù OLUWA.

13. Ni Hagai, òjíṣẹ́ OLUWA, bá jẹ́ iṣẹ́ tí OLUWA rán an sí àwọn eniyan náà pé òun OLUWA ní òun wà pẹlu wọn.

14. OLUWA bá fi ìtara rẹ̀ sí ọkàn Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí ọkàn Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wọn.

15. Ọjọ́ kẹrinlelogun, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà.

Ka pipe ipin Hagai 1