Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Habakuku 2:16-20 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ìtìjú ni yóo bò yín dípò ògo. Ẹ máa mu àmupara kí ẹ sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, ife ìjẹníyà tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún OLUWA yóo kàn yín, ìtìjú yóo sì bo ògo yín.

17. Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.

18. Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀!

19. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá.

20. Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Habakuku 2