Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 6:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Hamani lọ mú ẹ̀wù ati ẹṣin náà, ó ṣe Modekai lọ́ṣọ̀ọ́, ó gbé e gun ẹṣin, ó sì ń ké níwájú rẹ̀ bí ó ti ń fà á káàkiri gbogbo ìlú pé, “Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá lọ́lá.”

12. Lẹ́yìn náà, Modekai pada sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn Hamani sáré pada lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, ó sì bo orí rẹ̀.

13. Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.”

14. Bí wọ́n ti ń bá Hamani sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn ìwẹ̀fà ọba dé láti yára mú un lọ sí ibi àsè Ẹsita.

Ka pipe ipin Ẹsita 6