Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 4:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Hataki pada lọ ròyìn ohun tí Modekai sọ fún Ẹsita.

10. Ẹsita tún rán an pada sí Modekai pé,

11. “Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ati gbogbo eniyan ni wọ́n mọ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá lọ sọ́dọ̀ ọba ninu yàrá inú lọ́hùn-ún, láìṣe pé ọba pè é, òfin kan tí ọba ní fún irú eniyan bẹ́ẹ̀ ni pé kí á pa á, àfi bí ọba bá na ọ̀pá wúrà tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni náà ni wọn kò fi ní pa á. Ṣugbọn ó ti tó ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn tí ọba ti pè mí.”

12. Nígbà tí Modekai gbọ́ ìdáhùn yìí láti ọ̀dọ̀ Ẹsita,

13. ó tún ranṣẹ sí Ẹsita pada, ó ní, “Má rò pé ìwọ nìkan óo là láàrin àwọn Juu, nítorí pé o wà ní ààfin ọba.

Ka pipe ipin Ẹsita 4