Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 4:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Bí o bá dákẹ́ ní irú àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́, ati ìgbàlà yóo ti ibòmíràn wá fún àwọn Juu, ṣugbọn a óo pa ìwọ ati àwọn ará ilé baba rẹ run. Ta ni ó sì lè sọ, bóyá nítorí irú àkókò yìí ni o fi di ayaba?”

15. Ẹsita bá ranṣẹ sí Modekai, ó ní,

16. “Lọ kó gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa jọ, kí ẹ gba ààwẹ̀ fún mi fún ọjọ́ mẹta, láìjẹ, láìmu, láàárọ̀ ati lálẹ́. Èmi ati àwọn iranṣẹ mi náà yóo máa gbààwẹ̀ níhìn-ín. Lẹ́yìn náà, n óo lọ rí ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin, bí n óo bá kú, kí n kú.”

17. Modekai bá lọ, ó ṣe bí Ẹsita ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Ẹsita 4