orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 10 BIBELI MIMỌ (BM)

Títóbi Ahasu-erusi ati Modekai

1. Ọba Ahasu-erusi pàṣẹ pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jìnnà ati àwọn tí wọn ń gbé etíkun máa san owó orí.

2. Gbogbo iṣẹ́ agbára ati ipá rẹ̀, ati bí ó ṣe gbé Modekai ga sí ipò ọlá, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Media ati ti Pasia.

3. Modekai tíí ṣe Juu ni igbákejì sí Ahasu-erusi ọba. Ó tóbi, ó sì níyì pupọ láàrin àwọn Juu, nítorí pé ó ń wá ire àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ alaafia fún gbogbo wọn.