Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 1:12-18 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ìwẹ̀fà tí ọba rán jíṣẹ́ fún un, ó kọ̀, kò wá siwaju ọba. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru.

13. Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́.

14. Àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọn ni: Kaṣena, Ṣetari, ati Adimata, Taṣiṣi ati Meresi, Masena ati Memkani, àwọn ìjòyè meje ní Pasia ati Media. Àwọn ni wọ́n súnmọ́ ọn jù, tí ipò wọn sì ga jùlọ).

15. Ọba bi wọ́n pé, “Gẹ́gẹ́ bí òfin, kí ni kí á ṣe sí Ayaba Faṣiti, nítorí ohun tí ọba pa láṣẹ, tí ó rán àwọn ìwẹ̀fà sí i pé kí ó ṣe kò ṣe é.”

16. Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba.

17. Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’

18. Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i.

Ka pipe ipin Ẹsita 1