Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 7:14-24 BIBELI MIMỌ (BM)

14. nítorí pé èmi ati àwọn olùdámọ̀ràn mi meje ni a rán ọ lọ láti ṣe ìwádìí fínnífínní lórí Juda ati Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun rẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ,

15. ati pé kí o kó ọrẹ wúrà ati fadaka lọ́wọ́, tí ọba ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọrun Israẹli, tí ibùgbé rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

16. O níláti kó gbogbo wúrà ati fadaka tí o bá rí ní gbogbo agbègbè Babiloni, ati ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn alufaa bá fínnúfẹ́dọ̀ dá jọ fún Tẹmpili Ọlọrun wọn ní Jerusalẹmu.

17. “Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu.

18. Fadaka ati wúrà tí ó bá ṣẹ́kù, ìwọ ati àwọn eniyan rẹ, ẹ lò ó bí ó ti yẹ lójú yín ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun yín.

19. Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun ni kí o kó lọ sí Jerusalẹmu, níwájú Ọlọrun.

20. Bí o bá fẹ́ ohunkohun sí i fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun rẹ, gbà á ninu ilé ìṣúra ọba.

21. “Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un.

22. Ó láṣẹ láti gbà tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati ọtí waini, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati òróró, ati ìwọ̀n iyọ̀ tí ó bá fẹ́.

23. Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀.

24. A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun.

Ka pipe ipin Ẹsira 7