Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 2:37-56 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052)

38. Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247)

39. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017)

40. Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin

41. Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128)

42. Iye àwọn ọmọ àwọn aṣọ́nà:àwọn ọmọ Ṣalumu ati àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hatita ati àwọn ọmọ Ṣobai jẹ́ mọkandínlogoje (139)

43. Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili nìwọ̀nyí:àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa ati àwọn ọmọ Tabaoti;

44. àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Siaha ati àwọn ọmọ Padoni;

45. àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba ati àwọn ọmọ Akubu;

46. àwọn ọmọ Hagabu, àwọn ọmọ Ṣamlai ati àwọn ọmọ Hanani;

47. àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Gahari ati àwọn ọmọ Reaaya;

48. àwọn ọmọ Resini, àwọn ọmọ Nekoda ati àwọn ọmọ Gasamu;

49. àwọn ọmọ Usa, àwọn ọmọ Pasea, ati àwọn ọmọ Besai;

50. àwọn ọmọ Asina, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefisimu;

51. àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Akufa, àwọn ọmọ Hahuri,

52. àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Haṣa,

53. àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema,

54. àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa.

55. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí:àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda;

56. àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli;

Ka pipe ipin Ẹsira 2