Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 2:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana.Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí:

3. Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172)

4. Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372)

5. Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775)

6. Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812)

7. Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)

8. Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé marundinlaadọta (945)

9. Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (760)

10. Àwọn ọmọ Bani jẹ́ ẹgbẹta ó lé mejilelogoji (642)

11. Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbaata ó lé mẹtalelogun (623)

12. Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mejilelogun (1,222)

Ka pipe ipin Ẹsira 2