Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 10:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.

3. Nítorí náà, jẹ́ kí á bá Ọlọrun wa dá majẹmu pé a óo lé àwọn obinrin àjèjì wọnyi lọ pẹlu àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ, oluwa mi, ati àwọn tí wọ́n bẹ̀rù òfin Ọlọrun wa wí, kí á ṣe é bí òfin ti wí.

4. Ọwọ́ rẹ ni ọ̀rọ̀ yí wà; dìde nílẹ̀ kí o ṣe é. A wà lẹ́yìn rẹ, nítorí náà ṣe ọkàn gírí.”

5. Ẹsira bá dìde nílẹ̀, ó wí fún gbogbo àwọn olórí alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n búra pé wọn yóo ṣe gẹ́gẹ́ bí Ṣekanaya ti sọ, wọ́n sì búra.

6. Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé.

7. Wọ́n kéde jákèjádò Juda ati Jerusalẹmu pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé péjọ sí Jerusalẹmu.

8. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà, ẹnikẹ́ni tí kò bá farahàn títí ọjọ́ mẹta, yóo pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé.

9. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kẹta yóo fi ṣú, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọn ń gbé agbègbè Bẹnjamini ati Juda ni wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsan-an ni gbogbo wọn péjọ, wọn jókòó sí ìta gbangba níwájú ilé Ọlọrun. Gbogbo wọn ń gbọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n pè wọ́n fún ati nítorí òjò tí ń rọ̀.

10. Ẹsira, alufaa, bá dìde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣẹ̀ níti pé ẹ fẹ́ obinrin àjèjì, ẹ sì ti mú kí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli pọ̀ sí i.

11. Nítorí náà ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín, kí ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan náà ati kúrò lọ́dọ̀ àwọn obinrin àjèjì.”

12. Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè, wọ́n dáhùn pé, “Òtítọ́ ni o sọ, bí o ti wí ni a gbọdọ̀ ṣe.

13. Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi pọ̀, ati pé àkókò òjò nìyí; a kò lè dúró ní gbangba báyìí. Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ohun tí a lè parí ní ọjọ́ kan tabi ọjọ́ meji, nítorí ohun tí a ṣe yìí, a ti ṣẹ̀ gan-an

Ka pipe ipin Ẹsira 10