Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 5:9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ,nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀.

10. Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò,nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ.

11. Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni,ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda.

12. Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀,wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.

13. Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ,àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn!

14. Àwọn àgbààgbà ti sá kúrò ní ẹnubodè;àwọn ọdọmọkunrin sì ti dákẹ́ orin kíkọ.

15. Inú wa kò dùn mọ́;ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀.

16. Adé ti ṣíbọ́ lórí wa!A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀,

17. nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì;ojú wa sì ti di bàìbàì.

18. Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro;tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀.

19. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé,ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran.

20. Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata?Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́?

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 5