Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 4:18-22 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Àwọn eniyan ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò lè rìn gaara ní ìgboro.Ìparun wa súnmọ́lé,ọjọ́ ayé wa ti níye,nítorí ìparun wa ti dé.

19. Àwọn tí wọn ń lépa wa yáraju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ.Wọ́n ń lé wa lórí òkè,wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀.

20. Ẹ̀mí àwa ẹni àmì òróró OLUWA bọ́ sinu kòtò wọn,OLUWA tí à ń sọ nípa rẹ̀ pé,lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni a óo máa gbé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

21. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin ará Edomu,tí ń gbé ilẹ̀ Usi.Ṣugbọn ife náà yóo kọjá lọ́dọ̀ yín,ẹ óo mu ún ní àmuyó,ẹ óo sì tú ara yín síhòòhò.

22. Ẹ ti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín ní àjẹpé,ẹ̀yin ará Sioni,OLUWA kò ní fi yín sílẹ̀ ní ìgbèkùn mọ́.Ṣugbọn yóo jẹ ẹ̀yin ará Edomu níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín,yóo tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 4