Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 3:53-63 BIBELI MIMỌ (BM)

53. Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè,wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀.

54. Omi bò mí mọ́lẹ̀,mo ní, ‘Mo ti gbé.’

55. “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn.

56. O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé,‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’

57. O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́,o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’

58. “OLUWA, o ti gba ìjà mi jà,o ti ra ẹ̀mí mi pada.

59. O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi,OLUWA, dá mi láre.

60. O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn,ati gbogbo ète wọn lórí mi.

61. “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA,ati gbogbo ète wọn lórí mi.

62. Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi:ibi ni lojoojumọ.

63. Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó,wọn ìbáà dìde dúró,èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 3