Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 3:48-55 BIBELI MIMỌ (BM)

48. Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi,nítorí ìparun àwọn eniyan mi.

49. “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú miláì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi.

50. Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá,tí yóo sì rí wa.

51. Ìbànújẹ́ bá mi,nígbà tí mo rí ibi tí ó ṣẹlẹ̀sí àwọn ọmọbinrin ìlú mi.

52. “Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí ń dọdẹ mibí ìgbà tí eniyan ń dọdẹ ẹyẹ.

53. Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè,wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀.

54. Omi bò mí mọ́lẹ̀,mo ní, ‘Mo ti gbé.’

55. “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 3