Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 3:30-40 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí,kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án.

31. Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae.

32. Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa,yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu,gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

33. Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan láratabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí.

34. OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé,

35. kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo,

36. tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo.

37. Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀,láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i?

38. Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògoni rere ati burúkú ti ń jáde?

39. Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùnnígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

40. Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò,kí á tún ọ̀nà wa ṣe,kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 3