Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 3:2-11 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri.

3. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí,ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru.

4. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun,ó sì ti fọ́ egungun mi.

5. Ó dótì mí,ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri.

6. Ó fi mí sinu òkùnkùnbí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.

7. Ó mọ odi yí mi ká,ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí,kí n má baà lè sálọ.

8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́,sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi.

9. Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi,ó mú kí ọ̀nà mí wọ́.

10. Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀,ó lúgọ bíi kinniun,

11. Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 3